2 Samuel 7:1-16

Ìlérí Ọlọ́run si Dafidi

1 aÓ sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. 2Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”

3Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ̀ fún Dafidi láti kọ́ tẹmpili

4Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Natani wá pé:

5“Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé. 6Nítorí pé, èmi kò ì ti gbé inú ilé kan láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ọmọ Israẹli gòkè ti ilẹ̀ Ejibiti wá, títí di òní yìí, ṣùgbọ́n èmi ti ń rìn nínú àgọ́, fún ibùgbé mi. 7Ní ibi gbogbo tí èmi ti ń rìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ èmi ti bá ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli, tí èmi pa àṣẹ fún láti máa bọ́ àwọn ènìyàn mi àní Israẹli, sọ̀rọ̀ pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi kedari kọ́ ilé fún mi.” ’

8“Ǹjẹ́, nítorí náà, báyìí ni ìwọ yóò sì wí fún ìránṣẹ́ mi àní Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ti mú ìwọ kúrò láti inú agbo àgùntàn wá láti má tẹ̀lé àwọn àgùntàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli. 9Èmi sì wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí ìwọ ń lọ, èmi sá à gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, èmi sì ti sọ orúkọ rẹ di ńlá, gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá tí ó wà ní ayé. 10Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi ó sì gbìn wọ́n, wọn ó sì má gbé bí ibùjókòó tiwọn, wọn kì yóò sì sípò padà mọ́; àwọn ọmọ ènìyàn búburú kì yóò sì pọ́n wọn lójú mọ́, bí ìgbà àtijọ́. 11Àti gẹ́gẹ́ bí àkókò ìgbà tí èmi ti fi àṣẹ fún àwọn onídàájọ́ lórí àwọn ènìyàn mi, àní Israẹli, èmi fi ìsinmi fún ọ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.

“ ‘Olúwa sì wí fún ọ pé Olúwa yóò kọ ilé kan fún ọ:
12Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀. 13Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé. 14 bÈmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn. 15Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ. 16A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé: a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”

Copyright information for YorBMYO